Tope Alabi – Adake Dajo Lyrics

Tope Alabi – Adake Dajo Lyrics
Adake Dajo
Tope Alabi
    Lyrics copied!
    Adake Dajo Album Art
    "Adake Dajo." - Tope Alabi

    Album: Agbelebu
    Track No: 05

    Adake dajo
    On lo mo wa o, O mi wo wa w'okan
    Ohun gbogbo ti a gb'aye se
    On lo da ojiji mo wa o
    Ipilese aye wa ooo, at'opin re, O ri gbogbo koro
    Adake dajo
    On lo mo wa o, O n wo wa w'okan
    Ohun gbogbo ti a gb'aye se
    On lo da ojiji mo wa
    Ipilese aye wa ooo, at'opin re, O ri gbogbo koro
    Eni to da oju o, ko ni s'alairiran
    Olu to da eti o, ko le s'alaigboran
    Ko si koro loju Re, gbangba kedere lo ri gbogbo wa
    Adake dajo
    On lo mo wa o, O n wo wa w'okan
    Ohun gbogbo ti a gb'aye se
    On lo da ojiji mo wa
    Ipilese aye wa ooo, at'opin re, O ri gbogbo koro
    K'a ye s'esin, k'a ye pe e ni esin, k'a lo ja'wo pata
    A o le gan Olorun pelu 'gbagbo oju tori ko ni le gba wa
    A n fi ti'pa gboran si 'lana esin, ofin Olorun wa d'afieyin
    Opo dara loju, iwa won o dokan
    T'egbin t'idoti ko je k'adura opo onigbagbo o gba
    Ojiji t'Eleda da mo wa, o n s'afihan ohun ikoko o
    E o ni le gba'bode f'Olorun, onitohun a wule tan 'ra e pa
    Olorun alawopa, dakun ma wo mi pa
    Adake dajo
    On lo mo wa o, O n wo wa w'okan
    Ohun gbogbo ti a gb'aye se
    On lo da ojiji mo wa
    Ipilese aye wa ooo, at'opin re, O ri gbogbo koro
    Eemo to wo 'jo Olorun ti wa bureke, gbogbo aye di 'ranse Olorun
    At'eni Baba ran, at'eni ebi le de
    Woli osan gangan, iyen lo bi rere
    Ori pepe di 'gbale egungun
    At'alafose at'elepe
    Ogo ologo de ku t'on mi wo s'agbara
    Igbadi m be labe collar opo won
    Awon t'ogun nja t'on tori k'ogun o le se t'on wo 'nu ijo wa
    O ma se arakun laso gbagi logun to n kun ogun won
    Ab'e o ri ijo, ki Jesu to de ki ni yio da o
    Adake dajo
    On lo mo wa o, O n wo wa w'okan
    Ohun gbogbo ti a gb'aye se
    On lo da ojiji mo wa
    Ipilese aye wa ooo, at'opin re, O ri gbogbo koro
    E je k'a bi 'ra wa leere, gbogbo iranse Olorun pata
    Kini idahun si ibeere yi o
    Oro ijoba orun ti di 'waasu igbaani lenu wa
    Ere wo lonisowo agba n je ninu ise wa
    E gbo ere wo, ere wo, lOluwa n je
    A fowoleran O ma n wo wa o
    Ko ma ka 'se mi lai lere kankan
    Ki loo ro, ki loo so
    Nigba t'a ba p'oruko awon eniyan
    Ta o ba pe omo omo o
    Ki loo ro, ki loo so
    Ki loo ro, ki loo so
    Nigba t'a ba p'oruko awon eniyan
    Ta o ba pe omo omo o
    Ki loo ro, ki loo so
    T'a ba p'oruko ni'joba orun
    T'a pe won titi ti o de kan e o
    Eni to n toka s'omo apaadi, at'eyin to mo 'mo ile ologo
    T'on ba p'oruko ni'joba orun, t'on o ka mr census e ki loo ro
    Ki loo ro, ki loo so
    Nigba t'a ba p'oruko awon eniyan
    Ta o ba pe omo omo o
    Ki loo ro, ki loo so
    Onigbagbo ka ri mi ete eke
    Lati inu ijo je 'ra wa lese dede
    Adura at'aawe odi s'enikeji
    Ife ikoko lori pepe si pepe
    E o ranti O da ogbon o ju ogbon lo
    E o ba lako bi ibon lese-o-gbeji
    Ki loo ro, ki loo so
    Nigba t'a ba p'oruko awon eniyan
    Ta o ba pe omo omo o
    Ki loo ro, ki loo so
    Ojo nla, Adajo aye fere de
    Aiyiwapada idajo a ro
    K'onikaluku lo ye 'ra e wo
    Ibi t'o ba ku si, gb'adura k'o tun se
    Ko ma ba di ki loo ro
    K'enu ma wo ji, ailesoro
    Ki loo ro, ki loo so
    Nigba t'a ba p'oruko awon eniyan
    Ta o ba pe omo omo o
    Ki loo ro, ki loo so
    Eh eh eh eh eh eh mo wi t'emi o, ore ma di'ti
    Ko ma di'na orun mo 'ra e, o ti n f'ami han, Jesu o ni pe de
    Eru igi to n be loju re, lo gbe kuro, ko ye tenubole soro
    Lo ronu ko pa iwa da, ka si toro fun aanu
    K'a ju'wo ju'se k'a tuba f'Olorun,
    K'a le ba joba, k: a le ka wa mo won
    Ise wa laye yi ni lati wa ijoba Olorun
    Leyin re, ohun to ku, a o fi fun wa
    O n bo laipe, s'asaro aye re
    Ise wa laye yi ni lati wa ijoba Olorun
    Leyin re, ohun to ku, a o fi fun wa
    O n bo laipe, s'asaro aye re
    Ise wa laye yi ni lati wa ijoba Olorun
    Leyin re, ohun to ku, a o fi fun wa
    O n bo laipe, s'asaro aye re

    Writer(s): Patricia Temitope Alabi.

    All lyrical content displayed on this website is the intellectual property of its respective copyright holders. No ownership is implied, and no copyright infringement is intended.

    Get the Latest Lyrics Updates!

    Subscribe now and never miss a new song lyric update.

    Failed to load audio, please try again later.
    Failed to load song data.
    Invalid email address entered!
    Enter your suggestion!
    Thanks for your suggestion!
    Link copied
    Stop & exit Playlist

    Suggest a Lyrics Edit

    Stop Song
    Rhyto-Artwork

    Adake Dajo

    Rhyto
    × Add Rhyto to your Home Screen!