Tope Alabi – Oro Kan Soso Lyrics

Tope Alabi – Oro Kan Soso Lyrics
Oro Kan Soso
Tope Alabi
    Lyrics copied!
    Oro Kan Soso Album Art
    "Oro Kan Soso." - Tope Alabi

    Album: Oruko Tuntun
    Track No: 08

    Oro kan soso
    Oro kan soso, o le tun se, oro kan soso
    Ohun ti a ti f'oro baje ninu aye mi o
    Oro kan soso, o le tun se, oro kan soso
    Beeni mo wi
    Oro kan soso, o le tun se, oro kan soso
    Ohun ti a ti f'oro baje ninu aye mi o
    Oro kan soso, o le tun se, oro kan soso
    Oro laseda fi d'aye at'orun
    Ohun gbogbo to wa ninu e, oro lo fi da
    B'aye at'orun ba yi pada, oro l'Olorun yio wa titi lai
    Tori oro ledidi ohun gbogbo
    Oro kan soso, o le tun se, oro kan soso
    Ohun ti a ti f'oro baje ninu aye mi o
    Oro kan soso, o le tun se, oro kan soso
    Oro lagbara e wa wo'di oro aye
    Ohun t'aye n pe loro ni gbolohun
    Ninu oro aye ni won n so ofo
    Ninu oro won ni, ase
    Ohun oro aye n se fun aye
    'Jamba lo po ninu won
    Oruko t'aye ba p'oro ni yio je
    Ibi ni won fi n se fun 'ra won
    Eda gbogbo ti n gb'aye e ma ba mi bo o
    Ibudoko ero to n lo si irin ajo
    Laperosoko ti n p'ariwo
    E wole, hundred naira lowo ori enikan
    Onikaluku wole soko
    Loko ba kun ni won ba si
    Won m'ori le irin ajo won
    Igba t'an mi a gb'owo oko tan pata
    Baba kan lo ko to lohun o ni san'wo pe
    O san hundred naira, o fe gba forty naira pada
    Gbogbo ero to mbe ninu oko, won ko ha! wipe baba se bee ti gbo tele
    Conductor lohun o ni gba laabo, baba lohun o ni won kun
    Enikan ninu oko lohun a fi kun
    Baba ba ni ko ni dara f'eni ba fi kun
    Gbogbo ero to mbe ninu oko ba gb'enu won dake
    Igba baba de 'bi to n lo
    Lo ba wo conductor sokale loko, lo ba ni o gbe
    Ka to wi, ka to fo, ero ti pe le won lori
    Ijamba laye ma fi n wa (beeni)
    B'agbara aye ba ti n gun won (e o ni se won)
    B'ika ba n gun eniyan ibi, won a maa to'ja tase kiri beeni
    Oro ni won fi n ja, e wa wo'di oro t'aye n pon le
    Lo ba p'ase lati 'nu oro, t'a wa ninu Olorun ti a ko ri
    Ko to wi tan, conductor ti bo'so sonu
    Lo ba mo'ri le 'gbo
    S'e ti r'aye oro agbara aye, opelope arakunrin kan
    T'o m be ninu oko to j'omo Olorun, to m'oro iseda
    To da aye, to d'ohun gbogbo
    Oro Olorun to nipa oro eyi ti a ti ko wipe, ko s'ohun ija kan ti a se si o ti yio pa o lara
    Ati pe t'aa leni naa, ti n wi, to si n se, nigba ti Oluwa ko p'ase re o
    Nitorina, ni oruko Jesu Olugbala, conductor pada wa 'bi, wo'so k'ori e si pe
    Lara ba ro baba oloro aye, a b'e o r'oro to n gb'oro mi
    Bi ko ba se ti Jesu, opo eda lo ti d'eja ko s'awon won
    Oro kan soso, o le tun se, oro kan soso
    Ohun ti a ti f'oro baje ninu aye mi o
    Oro kan soso, o le tun se, oro kan soso
    Eniyan inu aye, e je k'a fura o
    Satani n s'oro bi agbon
    Elomiran ki a to bi won o, lowo awon ota ti te won
    Elomiran nigba t'a bi won tan, laarin egbe, nibi ise, owo ika t'a gbe leni lori ta o mo, lorisirisi ijamba ti n se ni
    E je ka gb'adura eniyan o
    K'aye ma f'oro won tun ni da
    Mo f'owo d'eleda mi mu
    K'ori mi ma gba 'bode oro o
    Oro kan soso to s'eda aye e, oro kan ni
    Oro kan soso to n gbe oro mi, oro kan soso
    Gbogbo ohun ti a ti f'oro baje ninu aye mi o
    Oro iseda, o so won di're pada, oro o
    Oro kan soso to s'eda aye e, oro kan ni
    Oro kan soso to n gbe oro mi, oro kan soso
    Gbogbo ohun ti a ti f'oro baje ninu aye mi o
    Oro iseda, o so won di're pada, oro o
    Oro kan soso to s'eda aye e, oro kan ni
    Oro kan soso to n gbe oro mi, oro kan soso
    Gbogbo ohun ti a ti f'oro baje ninu aye mi o
    Oro iseda, o so won di're pada, oro o

    Writer(s): Patricia Temitope Alabi.

    All lyrical content displayed on this website is the intellectual property of its respective copyright holders. No ownership is implied, and no copyright infringement is intended.

    Get the Latest Lyrics Updates!

    Subscribe now and never miss a new song lyric update.

    Failed to load audio, please try again later.
    Failed to load song data.
    Invalid email address entered!
    Enter your suggestion!
    Thanks for your suggestion!
    Link copied
    Stop & exit Playlist

    Suggest a Lyrics Edit

    Stop Song
    Rhyto-Artwork

    Oro Kan Soso

    Rhyto
    × Add Rhyto to your Home Screen!