Tope Alabi – Oruko Tuntun Lyrics

Tope Alabi – Oruko Tuntun Lyrics
Oruko Tuntun
Tope Alabi
    Lyrics copied!
    Oruko Tuntun Album Art
    "Oruko Tuntun." - Tope Alabi

    Album: Oruko Tuntun
    Track No: 04

    Olorun to da mi w'aye o, lo ni oruko mi amutorunwa
    Eleda to da mi leniyan lo so mi loruko akoko
    Emi lologo alayanmo ire, mo w'aye wa f'ogo Olorun han
    Aisiki ire, sabaabi idunnu lemi eniyan
    Olorun to da mi w'aye o, lo ni oruko mi amutorunwa
    Eleda to da mi leniyan lo so mi loruko akoko
    Emi lologo alayanmo ire, mo w'aye wa f'ogo Olorun han
    Aisiki ire, sabaabi idunnu lemi eniyan
    Eto Olorun ni emi je
    Aseda f'inu f'edo f'ife da mi
    O mo mi ni iri Ohun gangan
    Mi o ku si'bi kan, O da mi daradara
    Emi lamo t'owo Adaniwaye mo
    Eemi Aseda ni iwalaaye mi
    Oju ogo Re ni iriiran mi akoko
    Ipa lo fi se mi s'inu iya mi
    Ara nla owo Oga ogo ni mi
    Emi leniyan
    Olorun to da mi w'aye o, lo ni oruko mi amutorunwa
    Eleda to da mi leniyan lo so mi loruko akoko
    Emi lologo alayanmo ire, mo w'aye wa f'ogo Olorun han
    Aisiki ire, sabaabi idunnu lemi eniyan
    Irin ajo eda wa s'aye, esu, ota, elenini eniyan n duro
    Ami ibi to tele eda bo ni satani t'a le sokale lat'orun
    O n bu ramuramu, o n kanra, lo fi n fi'bi han eda leemo
    Eni ba w'aye (w'aye)
    Eeyan to n gb'aye (gb'aye)
    E ma sai bikita p'aye kun fun ibi
    Olorun to da wa, ko da wa tori ibi
    Olorun to da mi w'aye o, lo ni oruko mi amutorunwa
    Eleda to da mi leniyan lo so mi loruko akoko
    Emi lologo alayanmo ire, mo w'aye wa f'ogo Olorun han
    Aisiki ire, sabaabi idunnu lemi eniyan
    Ti Oluwa ni ile, ati ekun re
    Ohun gbogbo to da s'oke eepe lo dara
    Satani lo so won d'ibi
    Eniyan e ma se ran lowo
    Ma je k'an f'ibi so e loruko, ire ni'wo je o ma gbagbe
    Oruko a maa ro ni
    Jowo ma se bi alaigbon
    Ohun t'aa ba n je la o da
    Ara e gb'oruko t'awon eeyan n pe 'ra won (oruko t'on n pe 'ra won)
    E gb'oruko t'eniyan n pe 'ra re (e gb'oruko t'on n pe 'ra won)
    Oloriburuku, talaka n'on n pe 'ra won (oruko t'on n pe 'ra won)
    Agan, were, alaarun ni won n pe 'ra won (e gb'oruko t'on n pe 'ra won)
    Omugo, didinrin ni won n pe 'ra won (oruko t'on n pe 'ra won)
    Alayebaje, atoole n'on n pe 'ra won (e gb'oruko t'on n pe 'ra won)
    Aletilapa ni won n p'omo won (oruko t'on n pe 'ra won)
    Ah e o mo p'ohun t'a ba pe loruko o lagbara lori eda
    Ohun ti o n la koja ooo, jowo ma fi pe 'ra e mo
    Enikeni to ni 'dojuko isese kan, e ma fi pe loruko
    Ma f'epe san epe, maa ko oruko buburu, satani lo n je baun
    A ti d'ele aye na, dandan ni k'a laagun k'a to yo, sise pelu ero ire, wa a yo
    Awon elomiran a ni nile awon bi won o logun odun ni'gbeyawo won o ni le bimo
    Won a ni nile won (won kii le ko'le)
    Won a ni nile awon (won kii gbo k'on to ku)
    Idojuko won (n'on fi n pe 'ra won)
    A ni aisan to n se ohun (n lo pa 'ya ohun)
    Won a tun fun loruko (alaarun idile)
    Won a lohun gangan (logun ebi won)
    Eda n f'oruko isoro (p'oriki ara re)
    Won a ni b'o ti n se won (n'ile awon niyen)
    Eda e so'ro to dara jade, ero alaafia lOlorun ni si wa
    Ma f'ogun enu se 'ra e pa
    Pe 'ra e ni hun to fe je
    Oruko to dara lOlorun so mi
    Oruko to logo o lEleda n pe mi
    Oruko to dara ni emi n je
    Aseda mo mi ire
    Emi ako'rewaye
    Emi agb'ayesayo
    Mi o ya'gan lona kankan
    Aisiki ola, wura oro, ara owo Aseda, lemi eniyan
    Igbagbo n se pupo loro eda (alaisan ti o ni 'gbagbo ko le gba 'wosan)
    Ireti logun f'oruko tuntun (alainireti ko le kuro loju kan)
    Eda segun nipa oro enu re (iku ati iye wa lori ahon)
    Ma s'ahon d'ida fi sa ara e si wewe (wa a jere ohun to ba f'enu so)
    Eni to da'na s'aaro ti o gbe 'hun le'na (o daju ko ni 'hun se)
    O kan fe ya'na lasan ni, igbagbo ni yo ba ero e sise
    Ja ijangbara fun oruko rere, oruko lo n ro ni
    Oruko to dara l'Olorun so mi
    Oruko to logo o l'Eleda n pe mi
    Oruko to dara ni emi n je
    Aseda mo mi ire
    Emi ako'rewaye
    Emi agb'ayesayo
    Mi o ya'gan lona kankan
    Aisiki ola, wura oro, ara owo Aseda, lemi eniyan
    Eda to n gbe 'nu aye, yara pada s'odo Aseda
    On lo mo'di oro, On lo le yanju e
    F'Adaniwaye se edidi aye re, mura lati s'atunse gbogbo
    Ko lati je oruko t'aye n so ni, to n ba ayanmo wo 'jakadi
    Ore b'Olorun d'owo po o, k'aye e ko le toro
    Ore b'Olorun laja, ko le j'oruko tuntun
    Oruko to dara lOlorun so mi
    Oruko to logo o lEleda n pe mi
    Oruko to dara ni emi n je
    Aseda mo mi ire
    Emi ako'rewaye
    Emi agb'ayesayo
    Mi o ya'gan lona kankan
    Aisiki ola, wura oro, ara owo Aseda, lemi eniyan
    Obedi-Edomu j'oruko tuntun (o j'oruko tuntun)
    Bartholomew j'oruko tuntun (o je oruko tuntun)
    Jakobu j'oruko tuntun (o j'oruko tuntun)
    Dafidi j'oruko tuntun (o je oruko tuntun)
    Maria Magdaleni j'oruko tuntun (o j'oruko tuntun)
    Soolu j'oruko tuntun (o je oruko tuntun)
    Peteru apeja j'oruko tuntun ooo (o j'oruko tuntun)
    At'emi nipa eje odo aguntan, mo gba ire, to je ini mi pada
    Olorun to da mi w'aye o, lo ni oruko mi amutorunwa
    Eleda to da mi leniyan lo so mi loruko akoko
    Emi lologo alayanmo ire, mo w'aye wa f'ogo Olorun han
    Aisiki ire, sabaabi idunnu lemi eniyan
    Emi t'a da (Emi t'a da)
    Laworan Olorun (Olorun)
    Emi eda (Emi eda)
    Mo ri ojurere (Ojurere)
    Mo loore ofe to ga julo
    Emi lori (Emi lori)
    Mi kii se iru o (Lailai)
    Emi t'a da (Emi t'a da)
    T'ewa t'ogo Olorun (Olorun)
    Lat'odo Aseda o, ola mi o lakawe
    A ti fi oruko tuntun pe mi, emi
    A ti fi oruko tuntun pe mi, Amin
    A ti fi oruko tuntun pe mi, emi
    A ti fi oruko tuntun pe mi, Amin
    A ti fi oruko tuntun pe mi, emi
    A ti fi oruko tuntun pe mi, Amin

    Writer(s): Patricia Temitope Alabi.

    All lyrical content displayed on this website is the intellectual property of its respective copyright holders. No ownership is implied, and no copyright infringement is intended.

    Get the Latest Lyrics Updates!

    Subscribe now and never miss a new song lyric update.

    Failed to load audio, please try again later.
    Failed to load song data.
    Invalid email address entered!
    Enter your suggestion!
    Thanks for your suggestion!
    Link copied
    Stop & exit Playlist

    Suggest a Lyrics Edit

    Stop Song
    Rhyto-Artwork

    Oruko Tuntun

    Rhyto
    × Add Rhyto to your Home Screen!