Tope Alabi – Odara Ni Ife Lyrics

Tope Alabi – Odara Ni Ife Lyrics
Odara Ni Ife
Tope Alabi
    Lyrics copied!
    Odara Ni Ife Album Art
    "Odara Ni Ife." - Tope Alabi

    Album: Oruko Tuntun
    Track No: 02

    E fi'ba fun Un, e yin I o
    Awon angeli, won n yi ite Re ka
    Gbogbo eda eniyan, e yin I bo ti ye
    E fi'ba fun Un, e yin I o
    Awon angeli, won n yi ite Re ka
    Gbogbo eda eniyan, e yin I bo ti ye
    K'orin tuntun s'Oluwa iwo okan mi
    E ma yo n'nu Oluwa eyin olododo
    Nitori iyin ye fun Oluwa
    E fi duru yin Oluwa t'ohun t'eelo orin
    K'orin naa s'oke kikan k'aye ko gbo o
    Nitori ile aye kun f'aanu Re
    E fi'ba fun Un, e yin I o
    Awon angeli, won n yi ite Re ka
    Gbogbo eda eniyan, e yin I bo ti ye
    Emi t'a dalarr ti a dariji
    Emi t'Oluwa gba la, t'O se'gun fun
    Okan mi k'orin yin Oga ogo
    Awon angeli juba Re lojoojo
    Agbaagba lorun f'iba yi ite Re ka
    Pipe lo je ogo, lailakawe
    E fi'ba fun Un, e yin I o
    Awon angeli, won n yi ite Re ka
    Gbogbo eda eniyan, e yin I bo ti ye
    Mo f'eru gbe E ga, mo yin Oga ogo
    O so ibu omi po, O gba okun jo
    O s'oro, o si ti se mo yin O, Oluwa
    E fi'ba fun Un, e yin I o
    Awon angeli, won n yi ite Re ka
    Gbogbo eda eniyan, e yin I bo ti ye
    Didara ni ike, didara laabo
    Didara ni ife, didara laabo
    O po loore, O po ni'bukun o
    Mo wa f'iba fun O, Oba t'o n s'ohun gbogbo ninu ohun gbogbo
    Didara ni ike, didara laabo
    Didara ni ife, didara laabo
    O po loore, O po ni'bukun o
    Mo wa f'iba fun O, Oba t'o n s'ohun gbogbo ninu ohun gbogbo
    Ninu opo ife lo ragabo mi
    Oore ofe Re ni mo n je
    Ibukun Re to po, lo je k'emi po
    Ninu ogo Re lokan mi n yo
    Ohun gbogbo lO fi se 'ke mi
    Oba Onike, didara ni O
    Didara ni ike, didara laabo
    Didara ni ife, didara laabo
    O po loore, O po ni'bukun o
    Mo wa f'iba fun O, Oba t'o n s'ohun gbogbo ninu ohun gbogbo
    O gba mi lowo ogun idile
    Mariwo mi yo laarin igbago
    Ogun ibi a ti bi d'atemole
    Bi t'ota se po to won dake jeje
    Apenimadani, didara ni O
    Didara ni ike, didara laabo
    Didara ni ife, didara laabo
    O po loore, O po ni'bukun o
    Mo wa f'iba fun O, Oba t'o n s'ohun gbogbo ninu ohun gbogbo
    Alainironu o ni le dupe
    Mi o ni ya 'baramooreje
    Olori ogun to f'ife ja 'ja ikoro lori aye mi mo dupe
    Ope mi ka sai gun lailopin titi laye
    Aabo Re ti o ka lori ebi mi, komboki oore
    Olorun to dara ni'ke, ige, Iwo ni maa sin o
    Onife alailodiwon, Oloore mi O se
    Didara ni ike, didara laabo
    Didara ni ife, didara laabo
    O po loore, O po ni'bukun o
    Mo wa f'iba fun O, Oba t'o n s'ohun gbogbo ninu ohun gbogbo
    Igba ti ogun dide ija oloro (Iwo, Iwo, Iwo nikan lo n gbe mi ro)
    Igba ti eni a ro bi ore d'ota gbangba (Iwo, Iwo, Iwo nikan lo n gbe mi ro)
    Igba eti ore gbo ogun, to f'ese fe (Iwo, Iwo, Iwo nikan lo n gbe mi ro)
    Igba t'afeniferere o le rerin mo o (Iwo, Iwo, Iwo nikan lo n gbe mi ro)
    Igba t'ebi wa ninu ipaya ogun oro o (Iwo, Iwo, Iwo nikan lo n gbe mi ro)
    T'abanijiroro o le beere eni mo, o ma se (Iwo, Iwo, Iwo nikan lo n gbe mi ro)
    Olufe owon, Iwo nikan n mo ri o (Iwo, Iwo, Iwo nikan lo n gbe mi ro)
    Igba ti ile kan roro, ti ito enu gbe lau (Iwo, Iwo, Iwo nikan lo n gbe mi ro)
    Igba t'adura at'aawe di sisa, aisoje rara (Iwo, Iwo, Iwo nikan lo n gbe mi ro)
    Igba yi mo wa r'arisa eniyan bi won ti n jehun eni t'on pani (Iwo, Iwo, Iwo nikan lo n gbe mi ro)
    As'ologo asun mala lakun nirin ajo aye yi (Iwo, Iwo, Iwo nikan lo n gbe mi ro)
    Iwo to m'ooto oro, to mo 'bere to mo 'bi ti o pin si (Iwo, Iwo, Iwo nikan lo n gbe mi ro)
    Arinurode Olumoran okan lo yo mi o Ose (Iwo, Iwo, Iwo nikan lo n gbe mi ro)
    Didara ni ike, didara laabo
    Didara ni ife, didara laabo
    O po loore, O po ni'bukun o
    Mo wa f'iba fun O, Oba t'o n s'ohun gbogbo ninu ohun gbogbo
    Didara ni ike, didara laabo
    Didara ni ife, didara laabo
    O po loore, O po ni'bukun o
    Mo wa f'iba fun O, Oba t'o n s'ohun gbogbo ninu ohun gbogbo

    Writer(s): Patricia Temitope Alabi.

    All lyrical content displayed on this website is the intellectual property of its respective copyright holders. No ownership is implied, and no copyright infringement is intended.

    Get the Latest Lyrics Updates!

    Subscribe now and never miss a new song lyric update.

    Failed to load audio, please try again later.
    Failed to load song data.
    Invalid email address entered!
    Enter your suggestion!
    Thanks for your suggestion!
    Link copied
    Stop & exit Playlist

    Suggest a Lyrics Edit

    Stop Song
    Rhyto-Artwork

    Odara Ni Ife

    Rhyto
    × Add Rhyto to your Home Screen!